Wọn ti bura fun Gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi Gomina Ipinlẹ naa fun saa keji.

Gomina Akeredolu tọwọ bọ iwe ibura ati ẹjẹ lago mọkanla ku iṣẹju diẹ owurọ ana.

Igbakeji rẹ titun, Lucky Ayedatiwa naa ti bọsipo lẹyin ti oun naa ti fọwọ si iwe je bibura fun lati rọpọ igbakeji rẹ tẹlẹ too dije taako ninu eto idibo Gomina to koja nipinlẹ naa.

Akọroyin ileeṣẹ wa to wa nibi eto naa jabọ pe ilana abo COVID-19 jẹ ti tele san-san.

Babatunde Tiamiyu/Abdulmumin Ishola

Leave a Reply

Your email address will not be published.