Aṣaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Senator Bọla Tinubu ti sọ idi to fi ṣe pataki fawọn eeyan ilẹ Naijiria lati ṣe arawọn lọkan, ki aṣeyọri to nitumọ le fẹsẹ mulẹ lorilẹede yi.

Senator Tinubu sọ eyi lasiko to ṣabewo si Emir Kano, Aminu Ado-Bayero.

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko sọpe ilẹ Naijiria gbọdọ nifarada fun’rawon gẹgẹbi igbesẹ lati fẹsẹ isọkan mulẹ.

O tọkasi ipo t’orilẹede Naijiria wa bayi nile iṣọkan ati igbọra-ẹni ye fun idagbasoke orilẹede yi.

Ṣaaju Emir Kano, Ado-Bayero ṣeleri lati ṣiṣẹ tọọ agbega ati iṣọkan ilẹ yi.

Net/Babatunde Tiamiyu

Leave a Reply

Your email address will not be published.