Ọjọ́ burúkú èsù gbimi, lòjẹ́ fún àwọn tó n fi alùpùpù ṣiṣẹ́ ṣe, lágbègbè Mọlete, Òkè-Àdó nílu ‘bàdàn, nígbàtí ọkọ̀ tó n gbé epo diesel rọ́ lu arákùnrin kan tó sì ṣekupa.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tọ́rọna ṣojúrẹ ti ṣe lálàyé, ọkọ̀ àjàgbé ọ̀hún ló sọ ìjánu rẹ̀ nù tó sì kọ lu arákùnrin tón wa alùpùpù.

Awakọ̀ àjàgbé ọ̀hún ló ti sá àsálà fẹ́mi rẹ̀ kete tíṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, bóyá nítorí ìbẹ̀rùbojo káwọn èrò má gba ẹ̀san ẹni tó sekúpa lára fẹni.

Àwọn tó n wa alùpùpù ni wọn kọ̀ láti jk kí ọlọ́pa gbé òkú arákùnrin yi lọ, káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ le sin lójú ọjọ́.

Agbẹnusọ fún ilé ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi sọ pé iléṣẹ́ náà ti n ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé àwọn ọmọ ìsọta ko da àláfìa ìlú rú nítorí ìṣẹ́lẹ̀ náà.

Rotimi Ewenla/Babatunde Ishola

Leave a Comment