Gomina Ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti naka ikilọ sawọn ọdaran nipinlẹ naa lati ronu piwada tabi ki wọn foju jo dadasin niwaju ofin.

Gomina Fayẹmi fi ikilọ yi sita ni Ilu Ikere Ekiti nigbati o nsi agọ ọlọpa kan.

Gomina ẹni ti Olubadamọran Pataki re lori Ọrọ Aabo, Ọgagun Ẹbenezer Ogundana ṣoju fun, wa kilọ fawọn araalu lati yago fawọn iwa ọdaran, bẹẹ lo si tun wa tenumọ wipe ijọba ko ni faaye gba ki ẹnikẹni lati da ibagbepọ alaafia to wa nipinlẹ naa ru.

Gomina Fayẹmi fi kun wipe ọdaran eyikeyi tọwọ ba tẹ yoo jiya to ba tọ, to yẹ labẹ ofin.

Babatunde Tiamiyu

Leave a Comment