Ẹgbẹ awọn Dọkita to ntewiju lati nimọ si fi di akọṣẹmọṣẹ, lawọn ti ṣetan lati gunlẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke lọjọbọ ọsẹ yii, bijọba apapọ baa kuna lati dahun si ibere awọn.

Ninu atẹjade eyi ti wọn fisita lẹyin ipade ẹgbẹ naa nilu Abuja, Aarẹ ẹgbẹ naa, Dọkita Uyilawa Okhauaihesuyi ati akọwe agba, Dokita Jẹrry Isogun jumo fowosi nbeere fun sisan ajeele owo oṣu oju ẹsẹ, fawọn oṣiṣẹ to fimọ owo oṣu kẹta koṣu yi to pari.

Net/Babatunde Tiamiyu

Leave a Comment