Àwọn tó ńṣe ìdókowò lórí ẹ̀rọ ayélujára tamọ̀sí Cryptocurrency ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ si ńṣe ìdókowò wọn lábẹ́nú yàtọ̀ sí èyí táwọn èèyàn mọ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àṣẹ bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì, pé káwọn ilé-ìfowópamọ́ gbé àsùwọ̀n àwọn olùdókowò ohun tì páà.

Olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ kan, tíwọ́n ti ńkọ́ nípa ìdókowò wóòyi, Rume Ophi sọpé àwọn ilé-ìfowópamọ́ tí kansi àwọn olùdókowò Cryptocurrency lórí àṣẹ tí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ páà.

Lọ́jọ́ ẹtì ni iléṣẹ́ bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì pàṣẹ fáwọn ilé ìfowópamọ́ àti àwọn àjọ tó ni ńkan ṣe pẹ̀lú ìdókowò láti gbé àsùwọ̀n àwọn tó ńṣe ìdókóòwò orí ẹ̀rọ ayélujára, Criptocurrency ti páà.

Ó ní pẹ̀lú ìgbésẹ̀ yíì àwọn olùdókowò ti ba ṣiṣẹ okóòwò wọn lọ́nà míran yàtọ̀ sí àwọn àtẹ táwọn èèyàn mọ tẹ́lẹ̀ torípé wọ́n o le san owó láti pasẹ̀ àwọn àjọ tóní ǹkan ṣe pẹ̀lú ìdókowò mọ.

NET/Babatunde Tiamiyu

Leave a Reply

Your email address will not be published.