Àrẹ Muhammadu Buhari sọpé ìṣèjọba rẹ̀ yo tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe iṣẹ́ to kí ilẹ̀ Nàijírìa wà ní ìṣọ̀kan, kétò ọrọ̀ ajé rẹ̀ si tún dúró digbí tó sì tún jẹ́jẹ láti gbéná wojú àwọn tón domi àlàfìa ìlú rú.

Àrẹ Buhari sọ̀rọ̀ yí lásìkò tó n gba àwọn aṣojú ìgbìmọ̀ àgbàgbà láti ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe lálejò nílé Àrẹ nílu Abuja.

Àrẹ sọpé wíwà ní ìṣọ̀kan tíjọba àpapọ̀ yo si tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ tọ́ọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Borno, Ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Zulum, sọpé àwọn asájú yi ló wá nílu Abuja láti jẹ́ kí Àrẹ Buhari mọ àwọn ìpèníjà tí wọ́ ń dojú kọ lẹ́kùn wọn.

Net/Babatunde Tiamiyu

Leave a Reply

Your email address will not be published.