Oludari ikọ alaabo Amọtẹkun, Ajagunfẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti ni ahesọ ọrọ ni iroyin to nlọ kiri pe rukerudo n waye ni ijọba ibilẹ aarin gbungbun Ibarapa ati ariwa Ibarapa nipinlẹ yi.

Ajagbunfẹyinti Ọlayanju ẹni ti o sọrọ yi nilu Ibadan sọ wipe ikọ alaabo naa ti ṣeto silẹ lati lee daabobo ẹmi ati dukia awọn eniyan.

O tun ni awọn ohun ati fọnran kan to nlọ kiri lori erọ ayelujara jẹ lati ko ọkan awọn eniyan soke lasan ni, to si le da wahala silẹ lagbegbe nbaa.

Gẹgẹbi o wi, awọn agbẹ ati awọn ara ilu agbegbe ọun nba iṣẹ wọn lọ laisi idaamu tabi ifoya kankan.

Ajagunfẹyinti Ọlayanju fikun wipe ikọ alaabo naa ti nṣewadi iroyin iṣekupani kan ti wọn ni o ṣẹlẹ nibẹ to wa fi da awọn olugbe loju wipe wọn nipẹ foju awọn to huwa laabi ọun han ati idi ti wọn fi ṣe bẹe.

O wa rọ awọn eniyan iba lati tete maa fọrọ to ikọ Amọtẹkun ati awọn ajọ eleto abọ leti bi wọn ba wa ninu iṣoro eyekeyi.

Abdulmumeen Ishola

Leave a Reply

Your email address will not be published.