Ilẹ Amẹrica ati igbimọ ile Aṣofin apapọ nilẹ Naijiria to nrisi eto irina oju-ofurufu, ti ndaro awọn to farakasa ninu isele baalu awọn ọmọ ologun to ja lule ni toosi paapaako ofurufu Nnamidi Azikwe, nilu Abuja.

Ọrọ ibanikẹdun naa lo wa loju opo ẹro ayelujara Twitter Asoju ileṣẹ Amẹrica lorilẹede Naijiria, to ti nba ẹbi awọn to daraale latara iṣẹlẹ laabi naa ati ilẹ Naijiria lapapọ kẹdun.

Bakana, Alaga tekoto ile foro eto irina ofurufu, Sheitu Koko, wa ṣeleri pe iwadi to gbooro yoo bẹrẹ lati moohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Koko bẹẹ awọn eeyan ilẹ Naijiria lati mu suuru fun abajade iwaadi naa, aṣofin ọhun waa ni igbimọ ilẹ ọhun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn tọrọkan lati mọ oun to faa iṣẹlẹ naa ni pato.

Ninu atẹjade to fisita, Agbẹnuso Ileeṣe Ologun Oju Ofurufu, Ibikunle Daramọla sope ọkọ ofurufu ọhun to gbera lati Minna nipinlẹ Niger, lojakulẹ nilu Abuja lẹyin tọkọ baalu ọhun sọṣẹ lẹ, o fikun pe ọga Nileṣẹ Omo-Ogun Oju Ofurufu, Ogagun Oladayo Amoo ti paṣẹ iwadi ojuẹsẹ oun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Net/Abdulmumin Ishọla

Leave a Comment